WON TI RO AWON KRITENI NILE NIGERIA LATI GBE EMI ITORE AANU ATI IRONUJINLE WO PELU BI AYAJO OJO EERU TI BERE LONI LAGBAYE
Written by Christiana Akano on February 26, 2020
Pelu bawon Kristen lagbaye se asajoyo ayajo Ojoru Eeru lori ode yin, won ti fun omo Nigeria papajulo awon kristen nimoran lati sunmo Olorun ninu adura , ise ore ati emi arojinle.
Ojise Olorun ni, Very Rev Father Patrick Obayomi lo soro amoran naa ninu Ojo Ekeru pelu oniroyin wa Pius Sohe nilesin St John The Evangelist Catholic church, Ladipo Oshodi
Ojise Olorun naa woye pe ayajo Ojo Eeru yi je Ojo lati ya soto fun ibere Aawe Ologojo Ojo to je, koraenijanu atise ifarayin si Olorun.
O tenumo pe Ijo Aguda to ro gbogbo Kristeni lati wo aso dudu tabi so aso dudu mowo lati fi daro awon to lagbadi omo Esin o kuku, ijinigbe, sisoni dalainileloro atawon wa idunkoko moni lorile ede yi.
Very Rev Father Obayomi fikun oro re pe pataki ojoru eeru yii to maa nranileti pe erupe ni awa eeyan aa si pada di erupe.