AYA GOMINA IPINLE EKO FUN AWON OMODE LOUNJE NI ILU IGANDO

Written by on February 19, 2020

Aya  Gomina ti Ipinle Eko, Dokita Ibijoke Sanwo-Olu ti se ileri lati tesiwaju ati maa se iranlowo fun awon alaini ni Ipinle Eko papajulo, awon ti ijamba ina sele si ni Agbegbe Abule-Egba ni ibere Osu kinni Odun yi ti won si ko won lo si LASEMA IDO Camp, ni Igando.

Aya Gomina Sanwo-Olu ti ileri ni gbati won se abewo si awon ti ijamba ina naa selose ni LASEMA Resettlement Camp ni agbegbe Igando, pelu aya Igbakeji Gomina, Abileko Oluremi Hamzat.

Aya gomina se akiyesi botile jepe kosi eni to gbadura fun isele ibi ati ipe pajawiri naa, sugbon won mudaniloju pe ijoba ti se tan lati ko ju irufe isele pajawiri naa, pelu orisi Eka to n risi irufe isele pajawiri papajulo Ajo LASEMA.

Won Tesiwaju Ninu Oro Won nibi ti won ti ro awon olugbe ipinle Eko lati maa se akiyesi irufe isele yi ati lati tete maa pe awonEka to n ri si irufe isele pajawiri naa ko to di yanponyanrin.

Aya igbakeji Gomnina, Abileko Olufemi Hamzat ki awon ti isele ina naa sele si to wa ni Igando be won se se imototo ayikan won, to si gba won ni yanju, lati sokan giri, lati le se ise miran toripe, ti emi ba wa, ireti nbe.

Nigba to soro tire, Ajo Oga agba LASEMA, Dr. Olufemi Oke-Osanyintolu, dupe lowo Gomina babajide Sanwo-Olu fun akitiyan won lori isele ijamba nipa rira awon irinse to se dekun ijamba, tun rawo ebe lati ko Centra Resettlement camp miran si agbegbe Epe ti yio gba awon eyan pupo ni.

Ara awon ti isele naa kan, dupe lowo mgomina sanwo-Olu fun awon oun idera ti won pase, won ro ijoba lati rowon ni agbara nigba ti won wa ni ibi ipago lati bele irufe owo ti o wun won bose jepe won ti padanu gbogbo ohun ini won si ijamba ina naa.


Reader's opinions

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *Current track

Title

Artist

Background