IJOBA IPINLE EKO LOUN YOO PARI ISE AKANSE OMI TOWA NI ADIYAN
Written by Christiana Akano on October 11, 2019
Gomina Ipinle Eko, Ogbeni Babajide Sanwolu lawon yoo pari ise akanse omi to wa ni Adiyan lati le romi to ja gara mu fagooro omo Nigeria.
Ogbeni Sanwolu soro yi lasiko to kansi Ibudo Ise Akanse naa pelu awon iko isakoso re.
O salaye pe, ibudo omi naa lagbara lati pese omi ilo lopo yanturu leyi ti yoo tun kamikeke ninu ise idagbasoke, ise akanse ohun to bere lakoko Babatunde Fashola ni oun yoo pari laarin odun meji sigba taa wa yi.

Ajaboroyin Adeyemi Adesanya jabi pe, gomina tun kan si awon ibudo ise akanse ti iju ati Akuje lati mo ibi ti ise gbe duro lori e.